| De: |
"lanre" [ Profil ] |
| Sujet: |
E ku ojo meta
|
| Envoyé: |
Feb 1st, 2006 - 07:09:10 |
|
| |
Gbogbo omo egbe,A fi asiko yi ki gbogbo omo egbe YORUBA PARAPO pe e ku ewu odun tuntun, odun naa a sanwa si owo, omo, alaafia ti 'se baale oro, amin.Gegebi odo ti o'nsapa lati gbe ede ati asa Yoruba laruge, asiko tito lati dide lati so fun araye wipe omo bibi Yoruba niwa nipase ihuwasi ati isorosi wa.Melo ninu wa ni o tile nje oruko Yoruba ti awon Obi wa sowa, melo ni ongbiyanju lati ko awon ore re ti kiise omo Yoruba ni ede wa, melo ni o nje ounje ile tabi wo aso ibile wa yala ni Ilu wa Naijiriya tabi ni oke okun ?Awon Baba wa so wipe 'Bi onigba ba se gbe igba re ni won yio ba gbe'. Eyi jasi wipe ti a ba fi han nile loko wipe ede ati asa wa dara o si lewa lopolopo, awon ara, ore ati ojulumo yio nifesi nkan kan abi ikeji ninu asa wa naa.Idi eyi, aro gbogbo wa lati so ero okan wa lori bi a tile te siwaju.Ki i wa se eyi nikan, gbagede oro yi wa fun oniru'uru oro eyi ti yio ko wa ni eko. a le so oro lori Esin, Ijoba ati eto iselu, Oro aje, Iyan ati Oogun, Ero igbalode (Komputa),
Oro eleyameya, Ibasepo Okunrin ati Obinrin, ati beebe lo.E je ki gbogbo wa soji nipapa siso oro, sise akiyesi ati gbigba ara eni ni imoran.O ya, e dide ki e gbe raso.Ore yin tootoOlomu1
_______________________________________________
No banners. No pop-ups. No kidding.
Make My Way your home on the Web - http://www.myway.com
|
|